Exodus 25:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nibẹ̀ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọ̀rọ lati oke itẹ́-ãnu wá, lati ãrin awọn kerubu mejeji wá, ti o wà lori apoti ẹrí na, niti ohun gbogbo ti emi o palaṣẹ fun ọ si awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárin kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.