Exodus 25:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si ṣe ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi wurà bò wọn, ki a le ma fi wọn rù tabili na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fi igi kaṣíà ṣe òpó, fi wúrà bò wọ́n, kí o sì máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.