Exodus 25:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, kí o sì fi ṣe ọ̀pá fìtílà, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀.