Exodus 25:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa yìí ní iṣẹ́ ọnà bí òdòdó aláràbarà mẹta mẹta tí ó dàbí òdòdó alimọndi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ago mẹta ni ki a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi ati itanna li ẹka kan; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka ekeji, pẹlu irudi ati itanna: bẹ̃li ẹka mẹfẹ̃fa ti o yọ lara ọpá-fitila na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kọ́ọ̀bù mẹ́ta tí a se bí òdòdó alímọ́ńdì tí ó sọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni apá kan, mẹ́ta yóò sì wà ní apá kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà.