Exodus 26:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Aṣọ títa mẹ́wàá ni kí o fi ṣe inú àgọ́ mi, kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n dárà sí aṣọ náà pẹlu àwọ̀ aró, ati àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa, kí àwọn tí wọ́n bá mọ iṣẹ́ ọnà ya àwòrán Kerubu sí ara gbogbo aṣọ títa náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
IWỌ o fi aṣọ-tita mẹwa ṣe agọ́ na; aṣọ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ti on ti awọn kerubu iṣẹ ọlọnà ni ki iwọ ki o ṣe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣe àgọ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá, aṣọ ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ àti àsọ aláró, ti elésèé àlùkò, àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ni kí ó ṣe iṣẹ́ ọlọ́nà sí wọn.