Exodus 26:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka ni kí o ṣe sí àwọn ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan, kí ìtẹ́lẹ̀ meji wà fún àtẹ̀bọ̀ igi meji ninu olukuluku àkànpọ̀ igi náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si ṣe ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ meji na, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ meji na;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣe ogójì (40) ihà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìṣàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìṣàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.