Exodus 26:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ títa náà gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ina aṣọ-tita kan ki o jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ibò aṣọ-tita kan igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na ni ki o jẹ́ ìwọn kanna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ déédé ìgbọ̀nwọ́ mèjídínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀.