Exodus 27:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Fi idẹ ṣe ìkòkò láti máa kó eérú orí pẹpẹ sí, fi idẹ ṣe ọkọ́, àwo kòtò, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń gún ẹran ẹbọ ati àwo ìfọnná, idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò pẹpẹ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si ṣe tasà rẹ̀ lati ma gbà ẽru rẹ̀, ati ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀ ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo-iná rẹ̀ wọnni: gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ni iwọ o fi idẹ ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sìṣe abọ́ ìtẹ́dí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe.