Exodus 28:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, rán àwọn òkúta mejeeji mọ́ àwọn èjìká efodu náà, gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Èyí yóo mú kí Aaroni máa mú orúkọ wọn wá siwaju OLUWA fún ìrántí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si fi okuta mejeji si ejika ẹ̀wu-efodu na, li okuta iranti fun awọn ọmọ Israeli; Aaroni yio si ma rù orukọ wọn niwaju OLUWA li ejika rẹ̀ mejeji fun iranti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká èfòdì náà ní òkúta ìràntí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Árónì yóò sì máa ní orúkọ wọn ní wájú OLÚWA ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí.