Exodus 28:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oríṣìí òkúta mejila ni yóo wà, orúkọ wọn yóo dàbí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli; wọn yóo dàbí èdìdì, wọn yóo sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejila sí ara àwọn òkúta mejeejila, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Okuta wọnni yio si wà gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn; bi ifin edidi-àmi; olukuluku gẹgẹ bi orukọ rẹ̀ ni nwọn o wà fun ẹ̀ya Israeli mejejila.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òkúta méjìlá (12) yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.