Exodus 28:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, da òrùka wúrà meji mìíràn, kí o dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ àwọn èjìká efodu, níwájú ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi mejeji nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ti o kọjusi isolù rẹ̀, loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì se orùkọ wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù ẹ́fó dì méjèèjì ní ìṣẹ̀lẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó kọ́jú sí ìṣẹ̀lú rẹ̀, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù éfódì náà.