Exodus 28:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Fi òkúta Urimu ati òkúta Tumimu sí ara ìgbàyà ìdájọ́, kí wọn kí ó sì máa wà ní oókan àyà Aaroni, nígbà tí ó bá lọ siwaju OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni Aaroni yóo ṣe máa ru ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli sí oókan àyà rẹ̀, nígbà gbogbo níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si fi Urimu on Tummimu sinu igbàiya idajọ; nwọn o si wà li àiya Aaroni, nigbati o ba nwọle lọ niwaju OLUWA; Aaroni yio si ma rù idajọ awọn ọmọ Israeli li àiya rẹ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà ìwọ yóò sì mu Úrímù àti Tímímù sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Árónì nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú OLÚWA. Árónì yóò sì máa ru ohun ti a ń fi se ìpinu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn rẹ̀ nígbàgbogbo níwájú OLÚWA.