Exodus 28:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ya àwòrán èso pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀, sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan la àwọn àwòrán èso pomegiranate náà láàrin, yípo etí àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà, nísàlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni iṣẹti rẹ̀ nisalẹ ni iwọ o ṣe pomegranate aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, yi iṣẹti rẹ̀ ká; ati ṣaworo wurà lãrin wọn yiká;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣe pómégánátè ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó yí ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú aago wúrà láàrin wọn.