Exodus 28:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èyí ni Aaroni yóo máa wọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ alufaa rẹ̀, yóo sì máa gbọ́ ìró rẹ̀ nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ lọ níwájú OLUWA ati ìgbà tí ó bá ń jáde, kí ó má baà kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si wà lara Aaroni lati ma fi ṣiṣẹ: a o si ma gbọ́ iró rẹ̀ nigbati o ba wọ̀ ibi mimọ́ lọ niwaju OLUWA, ati nigbati o ba si njade bọ̀, ki o má ba kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Árónì gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń sisẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ níwájú OLÚWA àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.