Exodus 28:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Aaroni bá ń rú ẹbọ mímọ́, tí àwọn ọmọ Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA, kinní bí àwo pẹrẹsẹ yìí yóo máa wà níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si ma wà niwaju ori Aaroni, ki Aaroni le ma rù ẹ̀ṣẹ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yio si yàsimimọ́, ninu gbogbo ẹ̀bun mimọ́ wọn: on o si ma wà niwaju ori rẹ̀ nigbagbogbo, ki OLUWA ki o le ni inudidùn si wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó wà níwájú orí Árónì, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Árónì nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLÚWA.