Exodus 28:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn aṣọ tí wọn yóo rán náà nìwọ̀nyí; ọ̀kan fún ìgbàyà, ati ẹ̀wù efodu, ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ kan, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè kan tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí; fìlà kan, ati àmùrè. Wọn yóo rán àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi si li aṣọ ti nwọn o dá; igbàiya kan, ati ẹ̀wu-efodi, ati aṣọ igunwà, ati ẹ̀wu-awọtẹlẹ ọlọnà, fila, ati ọjá-amure: nwọn o si dá aṣọ mimọ́ wọnyi fun Aaroni arakunrin rẹ, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù èfòdì, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Árónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.