Exodus 28:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbé àwọn ẹ̀wù náà wọ Aaroni arakunrin rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì ta òróró sí wọn lórí láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si fi wọn wọ̀ Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; iwọ o si ta oróro si wọn li ori, iwọ o si yà wọn simimọ́, iwọ o si sọ wọn di mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí ìwọ ti fi àwọn aṣọ wọ̀nyí wọ Árónì arákùnrin rẹ, ìwọ yóò sì fi wọ àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlú, ìwọ óta òróró sí wọn ní orí, ìwọ yóò sì ya wọ́n sí mímọ́. Ìwọ yóò sì Sọ wọ́n di mímọ́, kí wọn kí o lè máa se iṣe àlùfáà.