Exodus 28:43 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ ṣòkòtò náà, nígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa ni ibi mímọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kú. Títí laelae ni òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa pa ìlànà yìí mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si wà lara Aaroni, ati lara awọn ọmọ rẹ̀, nigbati nwọn ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ, lati ṣiṣẹ ni ibi mimọ́; ki nwọn ki o má ba dẹ̀ṣẹ, nwọn a si kú: ìlana lailai ni fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọ̀ wọ́n nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ lọ tàbí nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ kí wọn kí ó má ba à dẹ́sẹ̀, wọn a sì kú. “Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún Árónì àti fún irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.