Exodus 29:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Fá gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati ẹ̀dọ̀ akọ mààlúù náà; mú kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n; kí o sun wọ́n lórí pẹpẹ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si mú gbogbo ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bori ẹ̀dọ, ati ti iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, iwọ o si sun u lori pẹpẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.