Exodus 29:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pa àgbò náà, kí o sì gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kí o tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn pẹlu. Lẹ́yìn náà, da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ara pẹpẹ yíká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki iwọ ki o pa àgbo na, ki o si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si eti ọtún awọn ọmọ rẹ̀, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn, ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n pẹpẹ na yiká.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sí pẹpẹ lórí àti ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.