Exodus 29:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mú lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lára pẹpẹ, sì mú ninu òróró tí wọ́n máa ń ta sí ni lórí, kí o wọ́n ọn sí Aaroni lórí ati sí ara ẹ̀wù rẹ̀, ati sí orí àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí ara ẹ̀wù wọn. Òun ati ẹ̀wù rẹ̀ yóo di mímọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹ̀wù wọn yóo sì di mímọ́ pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ ti o wà lori pẹpẹ, ati ninu oróro itasori, iwọ o si wọ́n ọ sara Aaroni, ati sara aṣọ rẹ̀, ati sara awọn ọmọ rẹ̀, ati sara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: ki a le sọ ọ di mimọ́, ati aṣọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n-ọn sára Árónì àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.