Exodus 29:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Mú ọ̀rá àgbò náà ati ìrù rẹ̀ tòun tọ̀rá rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun ati èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀; ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n ati itan rẹ̀ ọ̀tún, nítorí àgbò ìyàsímímọ́ ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si mú ọrá, ati ìru ti o lọrá ti àgbo na, ati ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ̀, ati iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, ati itan ọtún; nitori àgbo ìyasimimọ́ ni:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, iwe méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́).