Exodus 29:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó bá di alufaa dípò rẹ̀ yóo wọ àwọn aṣọ wọnyi fún ọjọ́ meje, nígbà tí ó bá wá sí ibi àgọ́ àjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o ba jẹ́ alufa ni ipò rẹ̀ ni yio mú wọn wọ̀ ni ijọ́ meje, nigbati o ba wá sinu agọ́ ajọ, lati ṣe ìsin ni ibi mimọ́ nì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje.