Exodus 29:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lojoojumọ ni kí o máa fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètùtù. O sì níláti máa rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún pẹpẹ náà nígbà tí o bá ń ṣe ètùtù fún un, ta òróró sí i láti yà á sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si ma pa akọmalu kọkan li ojojumọ́ ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu: iwọ o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, nigbati iwọ ba ṣètutu si i tán, iwọ o si ta oróro si i lati yà a simimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún-un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́.