Exodus 29:46 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun wọn, ti o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá, ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn: emi li OLUWA Ọlọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárin wọn. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn.