Exodus 3:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, tíí ṣe alufaa ìlú Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn aṣálẹ̀, títí tí ó fi dé òkè Horebu ní Sinai, tíí ṣe òkè Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mósè ń sọ́ agbo ẹran Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Mídíánì. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jínjìn nínú ihà. Ó dé Hórébù, òkè Ọlọ́run.