Exodus 3:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mósè pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”