Exodus 3:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun tún fi kún un fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó rán òun sí wọn. Ó ní orúkọ òun nìyí títí ayérayé, orúkọ yìí ni wọn óo sì máa fi ranti òun láti ìrandíran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run sì tún sọ fún Mósè pé, “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ‘OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù; ti rán mi sí i yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi láti ìran dé ìran.