Exodus 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó farahàn ọ́, ati pé, mo ti ń ṣàkíyèsí wọn, mo ti rí ohun tí àwọn ará Ijipti ti ṣe sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọ, ki o si kó awọn àgba Israeli jọ, ki o si wi fun wọn pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, ti Isaaki, ati ti Jakobu, li o farahàn mi wipe, Lõtọ ni mo ti bẹ̀ nyin wò, mo si ti ri ohun ti a nṣe si nyin ni Egipti:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lọ, kó àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, kí o sí sọ fún wọn, ‘OLÚWA Ọlọ́run Jákọ́bù; yọ sí mi, ó sì wí pé: Lóòótọ́ èmi ti ń bojúwò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Íjíbítì.