Exodus 3:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Wọn yóo gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, ìwọ ati àwọn àgbààgbà Israẹli yóo tọ ọba Ijipti lọ, ẹ óo sì wí fún un pé, ‘OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ti wá bá wa, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á lọ sinu aṣálẹ̀, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè rúbọ sí OLUWA, Ọlọrun wa.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si fetisi ohùn rẹ: iwọ o si wá, iwọ ati awọn àgba Israeli, sọdọ ọba Egipti, ẹnyin o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu pade wa: jẹ ki a lọ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki awa ki o le rubọ si OLUWA Ọlọrun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì yóò fetí sílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbààgbà yóò jọ tọ ọba Éjíbítì lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘OLÚWA, Ọlọ́run àwọn ará Hébérù ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti lọ rú ẹbọ sí OLÚWA Ọlọ́run.’