Exodus 3:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà n óo lo agbára mi láti fi jẹ Ijipti níyà, ń óo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀, nígbà náà ni yóo tó gbà pé kí ẹ máa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si nà ọwọ́ mi, emi o si fi iṣẹ-iyanu mi gbogbo kọlù Egipti ti emi o ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin eyinì li on o to jọwọ nyin lọwọ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárin wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.