Exodus 3:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
olukuluku obinrin yóo lọ sí ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ tí ó jẹ́ ará Ijipti ati àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóo tọrọ aṣọ ati ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka, ẹ óo sì fi wọ àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo sì ṣe gba gbogbo ìṣúra àwọn ará Ijipti lọ́wọ́ wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olukuluku obinrin ni yio si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ, lọwọ aladugbo rẹ̀, ati lọwọ ẹniti o nṣe atipo ninu ile rẹ̀: ẹnyin o si fi wọn si ara awọn ọmọkunrin nyin, ati si ara awọn ọmọbinrin nyin: ẹnyin o si kó ẹrù awọn ara Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun Sílífà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Éjíbítì.”