Exodus 3:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun tún fi kún un pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.” Mose bá bo ojú rẹ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Emi li Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu. Mose si pa oju rẹ̀ mọ́; nitoriti o bẹ̀ru lati bojuwò Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.” Nítorí ìdí èyí, Mósè fi ojú rẹ̀ pamọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti wo ojú Ọlọ́run.