Exodus 3:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà OLUWA dáhùn pé, “Mo ti rí ìpọ́njú àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní Ijipti, mo sì ti gbọ́ igbe wọn, nítorí ìnilára àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́, mo mọ irú ìyà tí wọn ń jẹ,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wipe, Nitõtọ emi ti ri ipọnju awọn enia mi ti o wà ni Egipti, mo si gbọ́ igbe wọn nitori awọn akoniṣiṣẹ wọn; nitoriti mo mọ̀ ibanujẹ wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Éjíbítì, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára.