Exodus 30:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba kà iye awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi ẹgbẹ wọn, nigbana li olukuluku ọkunrin yio mú irapada ọkàn rẹ̀ fun OLUWA wá, nigbati iwọ ba kà iye wọn; ki ajakalẹ-àrun ki o máṣe si ninu wọn, nigbati iwọ ba nkà iye wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún OLÚWA ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn kì yóò sún mọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn.