Exodus 30:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si gbà owo ètutu na lọwọ awọn ọmọ Israeli, iwọ o si fi i lelẹ fun ìsin agọ́ ajọ; ki o le ma ṣe iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì fi lé lẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú OLÚWA, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.”