Exodus 30:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Mú olõrùn didùn sọdọ rẹ, stakte, ati onika, ati galbanumu; olõrùn didùn wọnyi, pẹlu turari daradara: òṣuwọn kan na li olukuluku;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, óníkà, àti gálíbánúmù àti kìkì tùràrí dáradára, iye kan ni gbogbo rẹ,