Exodus 30:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si gún diẹ ninu rẹ̀ kunna, iwọ o si fi i siwaju ẹrí ninu rẹ̀ ninu agọ́ ajọ, nibiti emi o gbé ma bá ọ pade: yio ṣe mimọ́ julọ fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e ṣíwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín.