Exodus 30:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà meji fún pẹpẹ náà, jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àwọn òrùka náà ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé pẹpẹ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati oruka wurà meji ni ki iwọ ki o ṣe nisalẹ igbáti rẹ̀, ni ìha igun rẹ̀ meji, li ẹgbẹ rẹ̀ mejeji ni ki iwọ ki o ṣe e si; nwọn o si jasi ipò fun ọpá wọnni, lati ma fi gbé e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní ọ̀kánkán ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fí gbé e.