Exodus 31:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́ isimi mọ́; nitoripe mimọ́ ni fun nyin: ẹniti o ba bà a jẹ́ on li a o pa nitõtọ: nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ kan ninu rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a óò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá se iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a óò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.