Exodus 31:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíwájú sí i, èmi ti yan Óhólíábù ọmọ Áhúsámákì, ti ẹ̀yà Dánì, láti ràn án lọ́wọ́. Bákan náà, èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo paṣẹ fún ọ: