Exodus 32:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i pé Mose ń pẹ́ jù lórí òkè, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n tọ Aaroni lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ṣe oriṣa kan fún wa, tí yóo máa ṣáájú wa lọ; nítorí pé, a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI awọn enia ri pe, Mose pẹ lati sọkalẹ ti ori òke wá, awọn enia kó ara wọn jọ sọdọ Aaroni, nwọn si wi fun u pe, Dide, dá oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa lọ; bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mósè pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Árónì ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mósè tí ó mú wa jáde láti Éjíbítì wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí i.”