Exodus 32:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dá mi dá wọn, inú ń bí mi sí wọn gidigidi, píparẹ́ ni n óo sì pa wọ́n rẹ́, ṣugbọn n óo sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi jọwọ mi jẹ, ki ibinu mi ki o gbona si wọn, ki emi ki o le pa wọn run: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbòná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá.”