Exodus 32:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Mose bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí inú fi bí ọ tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ, àwọn tí o fi agbára ati tipátipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, OLUWA, ẽtiṣe ti ibinu rẹ fi gbona si awọn enia rẹ, ti iwọ fi ipá nla ati ọwọ́ agbara rẹ mú lati ilẹ Egipti jade wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Mósè kígbe fún ojú rere OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “OLÚWA, è é ṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Éjíbítì wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára?