Exodus 32:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ló dé tí o óo fi jẹ́ kí àwọn ará Ijipti wí pé, o mọ̀ọ́nmọ̀ fẹ́ ṣe wọ́n níbi ni o fi kó wọn jáde láti pa wọ́n lórí òkè yìí, ati láti pa wọ́n rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Jọ̀wọ́, má bínú mọ, yí ọkàn rẹ pada, má sì ṣe ibi tí o ti pinnu láti ṣe sí àwọn eniyan rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kini awọn ara Egipti yio ṣe sọ wipe, Nitori ibi li o ṣe mú wọn jade, lati pa wọn lori oke, ati lati run wọn kuro lori ilẹ? Yipada kuro ninu ibinu rẹ ti o muna, ki o si yi ọkàn pada niti ibi yi si awọn enia rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
È é ṣe tí àwọn ará Éjíbítì yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́ mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ.