Exodus 32:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wo ti Abrahamu, ati Isaaki, ati Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn tí o ti fi ara rẹ búra fún pé o ó sọ arọmọdọmọ wọn di pupọ gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run; o ní gbogbo ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí ni o óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn; ati pé àwọn ni wọn yóo sì jogún rẹ̀ títí lae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Israeli awọn iranṣẹ rẹ, ẹniti iwọ fi ara rẹ bura fun, ti iwọ si wi fun wọn pe, Emi o mu irú-ọmọ nyin bisi i bi irawọ ọrun, ati gbogbo ilẹ na ti mo ti sọ nì, irú-ọmọ nyin li emi o fi fun, nwọn o si jogún rẹ̀ lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ búra fún fúnraàrẹ: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”