Exodus 32:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó ti súnmọ́ tòsí àgọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí ère ọmọ mààlúù, ó sì rí àwọn eniyan tí wọn ń jó. Inú bí Mose gidigidi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ju àwọn wàláà òkúta náà mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ òkè náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi o ti sunmọ ibudó, o si ri ẹgbọrọmalu na, ati agbo ijó: ibinu Mose si ru gidigidi, o si sọ walã wọnni silẹ kuro li ọwọ́ rẹ̀, o si fọ́ wọn nisalẹ òke na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Mósè dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì ju pálí ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́ ní ìṣàlẹ̀ òkè náà.