Exodus 32:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ní, “Ẹ̀yin wo ni ẹ̀ ń ṣe ti OLUWA, ẹ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ọmọ Lefi bá kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún OLÚWA, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Léfì sì péjọ yí i ká.