Exodus 32:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wipe, Yẽ, awọn enia wọnyi ti dá ẹ̀ṣẹ nla, nwọn si dá oriṣa wurà fun ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Mósè padà tọ OLÚWA lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìsà wúrà fún ara wọn.