Exodus 32:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ alaafia wá, wọ́n bá jókòó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn lòpọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dide ni kùtukutu ijọ́ keji nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si mú ẹbọ alafia wá; awọn enia si joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rúbọ síṣun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.